Bí a Tilẹ̀ Ń Sunkún, A Kìí Ṣài Ríran!
Lọ́dun 1975 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ Kolera Kolej, àkọlé tí a túmọ̀ sí Kọ́lẹ́ẹ̀jì Onígbá Méjì nínú ìwé yìí. Ilé iṣẹ́ aṣèwé New Horn Press ní ìlú Ìbàdàn ló gbé e jádé. Òun sì ni ìwé ìtàn aláròsọ àkọ́kọ́ láti ọwọ́ Fẹ́mi Ọ̀ṣọ́fisan, ẹni tí gbogbo olóye ènìyàn mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n àti òǹkọ̀wé jàǹkàn. Eré aláṣehàn lórí ìtàgé ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣọ́fisan gbajúmọ̀ fún. Ṣàṣà ènìyàn ló mọ Ọ̀ṣọ́fisan ní olùkọ̀tàn. Kòtóǹkan ni iye ẹni tó mọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣọ́fisan gẹ́gẹ́ bí eléwì. Ṣùgbọ́n òǹkàwé tó bá fojú inú wo Kólẹ́ẹ̀jì Onígbá Méjì yóò rí i pé àṣehàn pọ̀ fún àwọn ẹ̀dá inú ìtàn náà; kódà bárakú ni ìṣe onídan jẹ́ fún èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èrò Onígbáméjì àti Oríle Iyá. Síwájú sí i, kò sí bí òǹkàwé kò ṣe ní kíyèsí ipa pàtaki ti ọ̀jọ̀gbọ́n akéwì, ẹ̀dá tó fẹ́ràn ajá rẹ̀ ju ènìyàn lọ, kó nínú ìtàn yìí. Ní tòótọ̀, ẹni wa fẹ́ràn obínrin dé góńgó; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó ní sí ajá rẹ̀ tayọ, ó ju góńgó lọ. Ìtumọ àlàyé tí mò ń ṣe ni pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé sísọ ni a sọ ìtàn inú Kólẹ́ẹ̀jì Onígbá Méjì, ọgbọ́n ìfihàn ìṣe àti ìrònú ìkéwì fìdí mulẹ̀ síbẹ̀. Dájúdájú, ìtàn tó lárinrin ni. Àràmàdà ẹ̀dá pọ̀ yanturu ní Onígbáméjì. Bí ṣàpà ti ń dàpọ̀ mọ́ lúrú, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará ìlú ń kó o jẹ wọ̀mù. Onírúurú ìṣe, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èyí tó já sí èṣe àti àṣìṣe, ló kún inú ìtàn yìí: ìdìbó àkọ́kọ́, ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ aṣòfin, kíkọ àdéhùn ìpìlẹ̀, ìṣẹ̀dá orin ìwúrí orílẹ̀ èdè, ìfilọ́lẹ̀ àsiyá ẹyẹ, ìfìjọbalọ́lẹ̀.
Ìtàn inú ìwé yìí fi yé wa pé orílẹ̀ èdè kan ń bẹ tí ó ń jẹ́ Orílé Iyá, níbi tí yunifásitì olókìkì kan gbé wà. Lójijì, àjàkálẹ̀ àrùn kan tí kò lẹ́rọ̀ bẹ́ sílẹ̀. Bí àmódi náà ti ń mú àwọn èrò fásitì ṣu láìdákẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ń mú wọn bì títí ẹ̀mí yóò fi jábọ́. Láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn tí kò gbóògùn yìí, àwọn aláṣẹ Orílé Iyá sọ yunifásitì ọ̀hún—Kọ́lẹ́ẹ́jì Onígbáméjì—di olómìnira àpàpàndodo. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìdáǹdè tí ibùgbé ìmọ̀ giga yii kò bèèrè fún di àjẹmógún fún un. Ṣùgbọ́n ìtura kò dé. Kàkà kó sàn ní Kọ́lẹ́ẹ́jì Onígbáméjì lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ nínú ìgbèkùn irọ́, ṣe ni àbìlù ń yí lu’ra wọn. Bí ìgbà tí ó jẹ́ pé àìsàn onígbáméjì gan an ló so ìjọba ró ni ọ̀ràn náà rí.
Àlọ́ àpamọ̀ kọ́ lèyì. Bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe àpagbè. Ohun tá à mọ̀, òun laà mọ̀. Irúfẹ́ ìtàn wo wá ni Kólẹ́ẹ̀jì Onígbá Méjì? Ó dá ni lóju pé ìtàn olówe ni. Òwe náà sì yà sọ́nà púpọ̀. Bó ti ń pòwe ìṣẹ̀lẹ̀, ló ń pòwe ìṣèlú, ló tún ń pòwe àróbá. Àróbá lásán sì kọ́, àróbá ìṣẹ̀lẹ̀ tòun tìṣèlú ni. Ìtàn inú Kólẹ́ẹ̀jì Onígbá Méjì kìí ṣe aláwòmọ́, nítorí pé kò sí ìlú tàbí orílẹ̀ kan tí a lè pé ní àwòkọ ìtan inú ìwe yìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dá ìtàn náà ń hùwà bí ẹ̀yà Yorùbá—àwọn kan nínú wọn tilẹ̀ lóríkì—ìṣesí gbogbo wọn, ìbáṣepọ̀ wọn, ìhà tí wọ́n kọ sí àkokò àti ìgbà, kò jọ ti ẹ̀yà kan pàtó. Ìpèsè fún ọjọ ọ̀la ṣe àjèjì sí wọn. Kò sí òpin, kò sí ìbẹ̀rẹ̀; agbedeméjì ni gbogbo nǹkan. Wọn kìí ṣe orò tàbí ọdún kankan nínú ayé ìtàn tí ìwé yìí gbé kalẹ̀. Kàyèfí ni gbogbo nǹkan wọn. Ibi mánigbàgbé pọ̀ bí ìgbẹ́ nínú ìtàn yìí: àjàkálẹ̀ àrùn gbẹ̀mí àìníye, láti orí àwọn aláṣẹ ìjọba títí lọ bá àwọn mẹ̀kúnnù tí kò lágbára; ìfipáṣèlú dàbí àdámọ́; bí ìjọba kan ti ń wó lulẹ̀ lòmíràn ń gun orí àléfà láì bìkítà fún ìlànà òfin; ọ̀wọ́n oúnjẹ gbòde; ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ aláìṣẹ̀ ni ìjoba kò-sẹ́ni-tí-yó-bi-wà jù sínú túbu làì wẹ̀yìn. Kí a má a sọ orílẹ̀ èdè ẹni sóko ọfà fún àníyàn orílẹ̀ èdè míràn kò tu irun kan lára àwọn olórí Kọ́lẹ́ẹ̀jì Onígbáméjì. Òǹkàwé tó bá gbẹ́kẹ̀ lé eléwì tó fẹ́ máa fi àkọsílẹ̀ ewì ṣe ìjẹ́rìí ọkàn rí i ní kòpẹ́kòpẹ́ pé wérewère òun náà pọ. Ni Kọ́lẹ́ẹ̀jì Onígbáméjì, àtìwọ̀fà, àtolówó, ète ìtànjẹ ni wọ́n ń pa láìdákẹ́. Ẹ̀tọ́, òótọ́, ati irọ́; kò yàtọ̀; ẹ̀ràn àti ẹ̀tàn di ọ̀kan; ọgbọgba sì ni irọ́ àti àwàdà. Bí àjàkálẹ̀ àrun ti ń gbé olóri fásitì ṣánlẹ̀ ni gbangba, eré onídan ni asọ̀tàn àti àwọn akóròyìnjọ pè é fún òǹkàwé. Rúdurùdu gbilẹ̀ lọ rẹpẹtẹ.
Adélékè Adéẹ̀kọ́
Comments
Post a Comment