Skip to main content

Posts

Showing posts with the label Yorùbá

Ìṣẹ̀ṣe, Àtúnṣe, Àtúndá

 | A Gathering of Feet | Photo by Tòkunbọ̀ Ọlálẹ́yẹ́ 1: Èrò kan ti ńjẹ mí lọ́kàn fún bí sáà mélòó. Ọ̀rọ̀ náà dá lórí ìfunpè àkíyèsí, àti ìfura, nípa ìlànà ìgbáyé ati ìgbàyè tí à ńpè ní Yorùbá lónìí, pàápàá ti àwọn aṣáájú ẹlẹ́sìn àti aláṣà nínú ìrísí yìí. Ẹṣin akitiyan tí mò ń wí jẹ mọ́ ìṣẹ̀ṣe. Bó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ìṣẹ̀ṣe ni. Èdè sísọ, ìṣẹ̀ṣe Yorùbá ni. Bó bá di ẹ̀ṣọ́, ìbáà jẹ́ ti ara, ìbáà jẹ́ ti oun mìíràn, ìṣẹ̀ṣe ni. Bó jẹ́ ìṣèlú, ìṣẹ̀ṣe yìí kan náà ni a máa ńké pè. Díẹ̀ lásán ni mo kà sílẹ̀ yìí. Ìṣèṣe sì kọ́ ló ńdà mí lọ́kàn rú. Ìhà tí àwọn oníṣẹ̀ṣe kọ sí ìṣẹ̀ṣe ló ńkọ mi lóminú nítorí pé, wọ́n ti sọ ìṣẹ̀ṣe fún’ra rẹ̀ di ká-bi-yín-ò-sí, wọ́n si fi òté bó-ṣe-wà-látètèkọ́ṣe dí i lẹ́nu.  2: Èmi a máa bá àwọn oníṣẹ̀ṣe jiyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ látàrí wípé wọ́n mọ odi àsàmọ̀sì yí abala oríṣi ìṣe kan ká, wọ́n sì pè é ní ìṣẹ̀ṣe. Abala tí wọ́n mọ odi ká náà kìí fọhùn, kìí fèsì ìbèrè láì fara ya, kì...

Ẹ̀tọ́ àti Ìṣe (2): Ǹjẹ́ Ẹ̀tọ́ Le Dínà Tàbí Dènà Ìṣe?

Ìbéèrè ni àkọlé àgbéyẹ̀wò wa lọ́tẹ̀ yìí: ǹjẹ́ ẹ̀tọ́ le dínà tàbí dènà ìṣe. Láì déènà pẹnu, ẹ̀tọ́ a máa kó ìṣe níjàánu.  Bí kò bá sí ìlànà ẹ̀tọ́, kò sí bí a ṣe fẹ́ díwọ̀n ìṣe. Níbikíbi tí òṣùnwọ̀n bá wà, ìdènà kò ní gbẹ́yìn. Kínni ẹ̀tọ́? Ìwé  Atúmọ̀ Ède Yorùbá  tí olóògbé Baàjíkí Abẹ́òkúta, Olóyè Isaac O[luwọ́lé], Délànọ̀, ṣe àkójọ̀ rẹ̀, tí ilé ìṣèwé Oxford University Press sì kó jáde ní 1958, fi yé ni wípé, “ẹ̀tọ́” já sí "èyí tí ó yẹ láti ṣe, èyí tí ó dára." Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ inú ìwé ògbufọ̀ tí ìjọ Sẹ́mẹẹ̀sì ṣe agbátẹrù rẹ̀, tí wọ́n sí kó jáde fún ìgbà èkínní ní 1913, ẹ̀tọ́ rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́nlé tàbí ajúwe wọ̀nyí: "tọ́, yẹ, dára."  Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tó fara mọ́ ẹ̀tọ́ ni "òtítọ́, òdodo, àǹfàní, ọ̀tún."  Ìwé ògbufọ̀ Sẹ́mẹẹ̀sì àti Atúmọ̀ Délànọ̀ fẹnu kò pé "tọ́" ni gbòǹgbò ẹ̀tọ́. Nídìí èyí, mo ṣe àyẹ̀wò pé kínni wọ́n sọ nípa ọ̀rọ̀ náà. Agbédègbẹyọ̀ ni ìwé Sẹ́mẹẹ̀sì, kìí ṣe atúmọ̀. Yíyí ni ó yí "tọ́" sí èdè gẹ̀ẹ́sì, kò túmọ̀ ...