Ìbéèrè ni àkọlé àgbéyẹ̀wò wa lọ́tẹ̀ yìí: ǹjẹ́ ẹ̀tọ́ le dínà tàbí dènà ìṣe. Láì déènà pẹnu, ẹ̀tọ́ a máa kó ìṣe níjàánu. Bí kò bá sí ìlànà ẹ̀tọ́, kò sí bí a ṣe fẹ́ díwọ̀n ìṣe. Níbikíbi tí òṣùnwọ̀n bá wà, ìdènà kò ní gbẹ́yìn.
Kínni ẹ̀tọ́? Ìwé Atúmọ̀ Ède Yorùbá tí olóògbé Baàjíkí Abẹ́òkúta, Olóyè Isaac O[luwọ́lé], Délànọ̀, ṣe àkójọ̀ rẹ̀, tí ilé ìṣèwé Oxford University Press sì kó jáde ní 1958, fi yé ni wípé, “ẹ̀tọ́” já sí "èyí tí ó yẹ láti ṣe, èyí tí ó dára." Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ inú ìwé ògbufọ̀ tí ìjọ Sẹ́mẹẹ̀sì ṣe agbátẹrù rẹ̀, tí wọ́n sí kó jáde fún ìgbà èkínní ní 1913, ẹ̀tọ́ rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́nlé tàbí ajúwe wọ̀nyí: "tọ́, yẹ, dára." Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tó fara mọ́ ẹ̀tọ́ ni "òtítọ́, òdodo, àǹfàní, ọ̀tún."
Ìwé ògbufọ̀ Sẹ́mẹẹ̀sì àti Atúmọ̀ Délànọ̀ fẹnu kò pé "tọ́" ni gbòǹgbò ẹ̀tọ́. Nídìí èyí, mo ṣe àyẹ̀wò pé kínni wọ́n sọ nípa ọ̀rọ̀ náà. Agbédègbẹyọ̀ ni ìwé Sẹ́mẹẹ̀sì, kìí ṣe atúmọ̀. Yíyí ni ó yí "tọ́" sí èdè gẹ̀ẹ́sì, kò túmọ̀ rẹ̀ ní èdè Yorùbá. Lójúu tèmi, kò sọ́nà níbẹ̀. Pọndanran ni mo yáa kọ́jú sí Délànọ̀. Àkosílẹ̀ tí a rí kà ninúu rẹ̀ rèé:
(1) Yẹ. Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti lọ?
(2) Gún, wà lí ọ̀kánkán. Ilà náà tọ́"
Délànọ̀ tẹ̀ síwájú, ó fi kún un pé:
(1) Báwí. Tọ́ ọmọ rẹ, yóò sì fún ọ ní ìsimi. [àgbàtọ́, olùtọ́] tọ́mọ
(2) Ṣẹ̀. Àjàí li ó kọ́ tọ́ Àjàí
Kò tán síbẹ̀. Atùmọ́ Délànọ̀ fún wa ní àwọn àpẹrẹ gbólóhùn méjì tó fi hàn pé "tọ́" dá lérí àwọn nǹkan mìíràn, pàápàá lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀:
1. ~ẹ̀fọ́: Já ewé ẹ̀fọ́ kúrò lára igi rẹ̀ (tọ́fọ̀ọ́.)
2. ~iṣu. Fi igi tọ́ okùn iṣu, lọ́ okùn iṣu mọ́ igi. Àgbẹ̀ tọ́ iṣu rẹ̀. (tọ́ṣu).
Bí àgbẹ̀ kò bá tọ́ irúgbìn, nílẹ̀ẹ́lẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ yóó máa jà ràn-ìn. Ọmọ tó bá lálàṣí olùtọ́, àfàìmọ̀ ni kò fi níí yawọ́. Ilà tí kò bá tọ́, dandan ni kó wọ́. Ìwadìí tó bá yege, yóò fi kedere ìwásẹ̀ hàn láì ṣègbè síbì kan. Àbájáde irúfẹ́ ìwadìí náà yóò tọ́, kò ní rọ́ sọ́tùnún, tàbí sósì, tàbí sẹ́gbẹ̀ẹ́; kò ní pọ̀n sókè tàbí ṣẹ́ sísàlẹ̀, Régé ni yóò gún. Títọ́ ni yóò tọ́.
Ní ìkadìí abala àgbéyẹ̀wò yìí, a lè pe iṣu gbíngbìn, ìwadìí, títọ́mọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ní ìṣe. Bí àgbẹ̀, òbí tàbí alágbàtọ́, àti olùwádìí kọ̀, tí wọn ò ṣẹ̀tọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n ṣe àgbákò ewu, kí ìdínà oríṣirísi—àṣìṣe, èṣe, àìmọ̀ọ́ṣe, àìríṣe—ká wọn lọ́wọ́ kò. Láì sí àníàní, àìmẹ̀tọ́ le dína ìṣe, yálà ìṣe ọ̀hún lẹ́wà, tàbí ó burẹ́wà. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìṣe tí kò sunwọ̀n ló lẹ́wà. Ìjàḿbá pọ̀ jọjọ nínú àìṣẹ̀tọ́.
Kí wá ni orísun ẹ̀tọ́? Ìṣe ha le jẹ́ orísun ẹ̀tọ́ bí? Ẹ jẹ́ ká sún àgbéyẹ̀wò yìí di ọjọ́ mìn-ín-ìn. Àmọ́ o, ẹ má gbàgbé pé èrò ni gbẹ̀gìrì, bá à bá rò ó, kò níí ki.
Ó dìgbà kan ná. Ire o. Láyọ̀ o.
Tọ́--ṣé o fẹ́ ẹ́ tọ́ mi níjà ni?
ReplyDeleteTọ́--Ìyàwó àgbẹ̀ ń tọ́ ẹ̀fọ́.
Tọ́--Àtòsí tọ́ sí ọ, mágùn ni ò yẹ ọ́.
Ẹ dákun kíni ẹ rí sọ sí èrò yì í?
Ẹ ṣeun, ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà. "Tọ́ ìjà" fara pẹ́ ìṣokùnfà. Ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni tàtọ̀sí. Èyí ṣe jẹ́? Kìkó làá kó àtọ̀sí, lílù làá lu mágùn. Ní ìlò òdè òní, a tún máa ńsọ pé ènìyàn, pàápàá onínàbì, kó mágùn. Àti mágùn o, àti àtọ̀sí èṣe ńlá ni wọn. Kí Èdùmàrè má jẹ̀ẹ́ ká ṣàgbákò ìkankan nínú àwọn ajogun méjèèjì.
ReplyDeleteDe̩re̩bà tí kò s̩'e̩to̩ fún o̩lo̩pa, tó fi aake ko̩rí wípé ìwé o̩ko̩ òhun jágaara...nje̩ às̩ìs̩e nlá ko̩ leleyi? Nje̩ e̩to̩ ni gbígbà àti fífún àbe̩te̩le̩? Àbi ìs̩e ni? Abí às̩ìs̩e ni?Àwo̩n èrò inú o̩ko̩ nko̩? Kíló ha mún wo̩n kàgbákò ìdádúró yi? Wo̩n ti s̩e̩to̩, wo̩n sanwó go̩bo̩yi fún de̩re̩ba, síbe̩ na wo̩n jèrè às̩ìs̩e, wo̩n pe̩ po d'é ibi is̩e̩ wo̩n!
ReplyDeleteẸ ṣeun, ṣeun, bí ojú ọ̀nà. Ìbéèrè ńlá lẹ bèèrè! Ọ̀ràn ló ṣẹlẹ̀ yìí. Bí ó bá jẹ́ òótọ́ ni ìwé ọkọ̀ pė, dírẹ́bà tí ṣẹ̀tọ́ nípa fífi wọ́n han ọlópàá. Ọlọ́pàá tó kọ̀ tí tẹ̀lé òfin ni kò ṣẹ̀tọ́, . Ẹni tó bá sì lu òfin rèé, ọ̀ràn ló dá. Ìjàm̀bá ló ṣe awakò yìí. Awakọ̀ yìí kò ṣe àṣìṣe rárá. Ọlọ́pàá arúfin ló ṣe sábàbí ìdádúró fún òun àti àwọn èrò inú ọkọ̀. Adínà ẹ̀tọ́ sì ni ọlópàá náà. Ọ̀daràn pọ́nbélé ni. Awakọ̀ àtí àwọn èrò inú ọkọ̀ kò ṣe àṣiṣe. Àgbákò ni wọ́n kò.
DeleteMo ṣàkíyèsí pé ẹ fẹ́ mọ̀ bóyà ìṣe tó bá ti di bárakú--tó sì ti di "àṣà," ó bófin mu o, kò bófin mu o--lè di orísun ẹ̀tọ́. Èmi kò rò bẹ́ẹ̀. Òfin wà láti dènà ibi. Òfin rírú kò lè jẹ́ orísun ẹ̀tọ́. N ó máa ṣàlàyé ìdí èyí làìpẹ́ jọjọ.
Ire o. Iyèkan an mi, Ọ̀gbẹ́ni Araòkanmí.