Aṣọ Tàbí Ènìyàn?
Lẹ́dà kan, mo gbọ́ pé, aṣọ ńlá kọ́ lènìyàn ńlá. Lẹ́dà kejì wọ́n tún fi yé mi pé aṣọ là ńkí, a à kí ‘nìyàn. (Ẹnu kòfẹ́sọ̀ àgbà kan ni mo tí kọ́kọ́ gbọ́ eléyìí ní nńkan bí ogún ọdún sẹ́hìn.) Èwo ni ká wá ṣe o? Èwo ni ká tẹ̀lé? Èwo ni ká gbàgbọ́. Gbólóhùn méjèèjì ha le jẹ́ òótọ́ bí? Àtakò kọ́ rèé!
Ó dá mi lójú pé àfiwé ni gbólóhùn méjèèjì. A tilẹ̀ lè pé wọ́n lówe. Gbogbo wa la sì mọ̀ pé àfiwé kìí ṣe òfin. Àfiwé yàtọ̀ sí ìṣẹ̀dálẹ̀. Òwe kìí ṣe orò. Àfiwé le jẹ́ àbàláyé. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tàbí ìmọ̀ tí àfiwé bá gbéró máa ńyí padà lóòrè kóòrè. Òjó yàtọ̀ sí òjò. Mẹ́táfọ̀ yàtọ̀ sí òtítọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ lè farasin sínú mẹ́táfọ̀. Ẹ̀ràn yàtọ̀ sí irọ́.
Kò sí ẹ̀dá alààyè àti olóye kankan tí kò mọ̀ pé aṣọ kìí ṣe ènìyàn, tàbí wí pé ènìyàn yàtọ̀ sí aṣọ. Dídá lènìyàn ńdá aṣọ tàbí ẹ̀wù. A kìi dá ènìyàn bí ẹni ńdáṣọ. Ènìyàn lè wọ aṣọ tàbí ẹ̀wù. Èmi kò rò pé aṣọ lè wọ ènìyàn bí ènìyàn ṣe ńwọ aṣọ.
Ènìyàn a máa wọ aṣọ láti bo àṣírí ìhòhò, láti ṣe fújà láwùjọ, fún ìdáàbòbò ara, fún ẹ̀ṣọ́ tàbí oge ṣíṣe. Ènìyàn lè wọ aṣọ iṣẹ́, aṣọ ìgbàlódé. Aṣọ àwọ̀sùn ńbẹ. Aṣọ ìjà wà. Ìran ènìyàn níí wọ aṣọ, torí pé ènìyàn ló ńṣẹ̀dá aṣọ. Ìran aṣọ kìí wọ ènìyàn. Ní ṣokí, láìsí ènìyàn, aṣọ kò sí. Àmúlò ni aṣọ jẹ́ fún ènìyàn. Ènìyàn ṣáájú aṣọ. Kódà, a lè sọ pé énìyàn làgbà.
Lọ́nà mín-ìn ẹ̀wẹ̀, pàápàá jùlọ láwùjọ ọmọnìyàn, aṣọ ni aṣáájú. Ènìyàn tí a kò bá kọ́kọ́ rí ẹ̀wù lára rẹ̀, ìhòhò gedegbe ni a máa bá onítọ̀hún. Bí kò bá níbá, olóye ènìyàn kìí rìnde ìhòhò. Ọmọlúwàbí gbọdọ̀ da nǹkan bora ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìlò, ẹ̀yọ, àti ẹ̀ṣọ́ tí ó bá ìfẹ́ àwùjọ dọ́gba. Nípa èyí, a lè tànmọ́ọ̀ pé aṣọ tàbí ẹ̀wù jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èròjà tí ńsọ ẹ̀dá dènìyàn láwùjọ. Ẹ̀dá tí àwùjọ bá fi jọba yóò dádé, ọdẹ yóò wọ bọ́dẹwọ́tìí, onífàájì yóò wẹ̀wù afẹ́. Ní ìlànà ìhùwàsì ẹ̀dá, ajúwe ènìyàn ni aṣọ. Olùdàrí ìṣesí ló tún jẹ́ bákan náà. Ìdí nìyí tí a fi ńyíkàá fún orí adé, tí a fi ńṣe sàdáńkàtà fún ìjòyé, tí kòròfo fi ńbẹ́rí fún sajiméjọ̀ ni gbàgadè. Ó dàbí ẹni pé aṣọ ńla lèèyàn ńlá!
Ǹjẹ aṣọ lènìyàn? Rárá o. Ọ̀tọ̀ lèèyàn iyi. Ọ̀tọ̀ laṣọ iyì. Aṣọ ẹ̀tẹ́ wà. Aṣọ ìyà wá. Èèyàn ńlá le dá agbádá ẹ̀tẹ́. Ènìyàn giga lè wọ dàǹdógó àbùkù. Ẹni kúkúrú le dé fìlà gogoro. Ọ̀tọ̀ lèèyàn iyì, ọ̀tọ̀ lẹ̀wù iyi.
Èròjà ènìyàn yàtọ́ sí èròja aṣọ.
Èròjà ènìyàn yàtọ́ sí èròja aṣọ.
Ọrọ Nla
ReplyDelete