Ìbéèrè ni àkọlé àgbéyẹ̀wò wa lọ́tẹ̀ yìí: ǹjẹ́ ẹ̀tọ́ le dínà tàbí dènà ìṣe. Láì déènà pẹnu, ẹ̀tọ́ a máa kó ìṣe níjàánu. Bí kò bá sí ìlànà ẹ̀tọ́, kò sí bí a ṣe fẹ́ díwọ̀n ìṣe. Níbikíbi tí òṣùnwọ̀n bá wà, ìdènà kò ní gbẹ́yìn. Kínni ẹ̀tọ́? Ìwé Atúmọ̀ Ède Yorùbá tí olóògbé Baàjíkí Abẹ́òkúta, Olóyè Isaac O[luwọ́lé], Délànọ̀, ṣe àkójọ̀ rẹ̀, tí ilé ìṣèwé Oxford University Press sì kó jáde ní 1958, fi yé ni wípé, “ẹ̀tọ́” já sí "èyí tí ó yẹ láti ṣe, èyí tí ó dára." Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ inú ìwé ògbufọ̀ tí ìjọ Sẹ́mẹẹ̀sì ṣe agbátẹrù rẹ̀, tí wọ́n sí kó jáde fún ìgbà èkínní ní 1913, ẹ̀tọ́ rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́nlé tàbí ajúwe wọ̀nyí: "tọ́, yẹ, dára." Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tó fara mọ́ ẹ̀tọ́ ni "òtítọ́, òdodo, àǹfàní, ọ̀tún." Ìwé ògbufọ̀ Sẹ́mẹẹ̀sì àti Atúmọ̀ Délànọ̀ fẹnu kò pé "tọ́" ni gbòǹgbò ẹ̀tọ́. Nídìí èyí, mo ṣe àyẹ̀wò pé kínni wọ́n sọ nípa ọ̀rọ̀ náà. Agbédègbẹyọ̀ ni ìwé Sẹ́mẹẹ̀sì, kìí ṣe atúmọ̀. Yíyí ni ó yí "tọ́" sí èdè gẹ̀ẹ́sì, kò túmọ̀ ...