| A Gathering of Feet | Photo by Tòkunbọ̀ Ọlálẹ́yẹ́ |
1: Èrò kan ti ńjẹ mí lọ́kàn fún bí sáà mélòó. Ọ̀rọ̀ náà dá lórí ìfunpè àkíyèsí, àti ìfura, nípa ìlànà ìgbáyé ati ìgbàyè tí à ńpè ní Yorùbá lónìí, pàápàá ti àwọn aṣáájú ẹlẹ́sìn àti aláṣà nínú ìrísí yìí. Ẹṣin akitiyan tí mò ń wí jẹ mọ́ ìṣẹ̀ṣe. Bó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ìṣẹ̀ṣe ni. Èdè sísọ, ìṣẹ̀ṣe Yorùbá ni. Bó bá di ẹ̀ṣọ́, ìbáà jẹ́ ti ara, ìbáà jẹ́ ti oun mìíràn, ìṣẹ̀ṣe ni. Bó jẹ́ ìṣèlú, ìṣẹ̀ṣe yìí kan náà ni a máa ńké pè. Díẹ̀ lásán ni mo kà sílẹ̀ yìí. Ìṣèṣe sì kọ́ ló ńdà mí lọ́kàn rú. Ìhà tí àwọn oníṣẹ̀ṣe kọ sí ìṣẹ̀ṣe ló ńkọ mi lóminú nítorí pé, wọ́n ti sọ ìṣẹ̀ṣe fún’ra rẹ̀ di ká-bi-yín-ò-sí, wọ́n si fi òté bó-ṣe-wà-látètèkọ́ṣe dí i lẹ́nu.
2: Èmi a máa bá àwọn oníṣẹ̀ṣe jiyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ látàrí wípé wọ́n mọ odi àsàmọ̀sì yí abala oríṣi ìṣe kan ká, wọ́n sì pè é ní ìṣẹ̀ṣe. Abala tí wọ́n mọ odi ká náà kìí fọhùn, kìí fèsì ìbèrè láì fara ya, kìí ṣí, kìí gbó, kìí ṣá, kìí díbàjẹ́. Láé àti láéláé ni gbogbo ohun tí ó dáṣẹ̀ẹ́ rẹ̀. Sàmọ́ni kankan kò nípá láraa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìṣípòpadà ibùgbé kò lágbára lóríi rẹ̀. Bi mo bá bèèrè pé irú ìṣẹ̀ṣe wo wá lèyí tí kò le bá ìgbà jọ tàbí bá a mu, wọn à sí dá mi lóhùn pé ìṣẹ̀ṣe Yorùbá ni.
3: Ẹ má ṣì mí kà o. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má ṣì mí gbọ́. Ìṣẹ̀ṣe ńbẹ. Gbogbo ogun ẹnu tí mò ńgbé jẹ mọ àlàyé ìlànà wíwà ìṣẹ̀ṣe. Lérò tèmi, kò sí ìṣe tí ìbí rẹ̀ ṣẹ̀yìn ẹ̀dà, ẹ̀dá, àti àtúnṣe. Ìṣẹ̀ṣe le jẹ́ ohun titun, ohun mérìírí, nígbà kan. Ṣùgbọ́n bí a bá ṣe ìwadìí, yóò yé wa pé àwọn ọ̀mọ̀ràn tàbí amòye kan ló pa eéjì pọ̀ mọ́ ẹẹ́ta. Ní tòótọ́, ohun titun yìí le má jẹ́ ẹ̀dà pọ́nbélé tí ohun mìíràn kan pàtó ṣu yọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ìṣẹ̀ṣe kò dá wà, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àpapọ̀, àrọpọ̀, àdàlù, àgúnpọ̀, àlùpọ̀, àlọ̀pọ̀, àlọ́pọ̀, àsopọ̀, ìyọkúrò, àfikún, ẹ̀yọ́, èjó, àti àwọn ìgbésẹ̀ yanturu mìíràn tí a kó dárúkọ, ni àwọn onímọ̀ fi ń ṣe (ọdẹ, ìlú, òkú, orò, ètò, ẹ̀sìn), tí wọ́n fi ń rọ (ọkọ́, ẹ̀rọ), fi ń dá (ifá, oko), fi ń pa (ìtàn, àlọ́, ènìyàn, ọ̀tá), fi ń hun (aṣọ), tàbí dó (ìlú, ibùdó). Ìṣẹ̀ṣe jẹ́ àkọ́dá tàbí àkọ́ṣe irúfẹ́ gbogbo àwọn ohun tí mo kà sílẹ̀ yìí. (Ó yẹ kí àkíyèsí fi hàn pé gbogbo rẹ̀ ló sì jẹ mọ́ ìlànà ètò nípa àjọbí àti àjọgbé láwùjọ ènìyàn, láti inú ìyẹ̀wù títí dé ilẹ̀ kòwárí.)
4. Bí a bá gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò síwájú sí i, a ó ríi pé, ẹ̀ẹ̀kan ni ìṣẹ̀ṣe máa ńjẹyọ. Kété lẹ́hìn ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́, ìgbésẹ̀ ẹ̀dà tàbi àṣeṣetúnṣe ló kù. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a kò ní lè mọ nǹkan ìṣẹ̀ṣe ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí ìṣe alárà. Àwòfín, àkọfín, àti àkàfín nípa àwùjo̧ ọmọ ènìyàn jákèjádò fi yé wa pe gbogbo ìṣe ẹ̀dá ló gbọ́dọ̀ sée dà rọ. Ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ mi ni pé, bí a bá fẹ́ dúró lórí òtítọ́, èyí tí wọ́n ńpè ní gàsíkíyà lédè Awúsá, àtùndá ni gbòǹgbò ìṣẹ̀ṣe. Ẹ jẹ́ kí a máa níran pé àtúnṣe, tàbí àtúndá, ni ìpilẹ̀ ìṣẹ̀ṣe.
5. Èrò témi ni pé, dídàrọ, tàbí àṣeetúnṣe nìkàn, kò ní imi tó fún àgbéró ìṣẹ́ṣe. Àyè, ìgbàyè, àlàyé, àti ètò ìṣàlàyé gbọ́dọ̀ wà fún àtúnṣe àti àtúndá.
Ire ni o
Comments
Post a Comment