Ìyà àìní ìwé ńjẹ wá ni ilẹ̀ wa, àìsàn rẹ̀ tilẹ̀ ńṣe wa pẹ̀lú. Ìwé kíkọ àti ìwé kíkà ni ọ̀kan nínú ohun tí ó sọ àwọn òyìnbó di ẹni ńlá àti ẹni alágbára; ohun tí àwọn ará ìṣájú ṣe, òun ni àwọn ará ẹ̀yìn ńlò tí wọ́n sì ńtúnṣe, ọgbọ́n sì túbọ̀ ńwọ inú ọgbọ́n. Ó yẹ ká gbìyànjù láti fi ìpilẹ̀ ọgbọ́n ìwé lélẹ̀ ní èdè wa.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ìbílẹ̀ wà tó ti ní èrò yìí ní ọkàn, bí irú àwọn tó ṣe Ìwé Kíkà kinní, kejì, kẹta, àti ẹ̀kẹrin; ṣùgbọ́n bí àwọn ìwé yìí ti jẹ́ ohun olóyelórí àti ohun àríyọ̀ tó, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ni ohun tí a yí láti èdè òyìnbó. Kìí ṣe pé ká má yìí ìwé rere tí ó bá wà ní èdè Òyìnbó sí èdè wa kò dára, ṣùgbọ́n a rò pé yóò dára púpọ̀ bí a ba ní ìwé tí a ṣe fún ara wa, […]
Ní ọ̀wọ́ yìí ni a lè ka Ìwé Àlọ́ sí, ìwé kékeré tí ẹgbẹ́ wa kan D.B. Vincent, ọmo-ìbílẹ̀ wa ṣe ní kòpẹ́. Ṣájú ìwé yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kéré ni, kò sí irú rẹ̀ tí ẹnìkanṣoṣo dáwọ́lé tí ó sì ṣe, tí ó jẹ́ ohun tí a kò yí láti èdè òyìnbó, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ìwé tí ó yan ni lójú bíi rẹ̀ nígbàtí ó jádé. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn rò pé èdè gẹ̀ẹ́sì ló yẹ kí a máa lò títí, tàbí pé ìwé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkanṣoṣo tó láti lò ní èdè wa; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ba ní òye lè rí i pé èrò búburú ni èyí já sí. Èdè gẹ̀ẹ́sì dára púpọ̀, ó sì ní iye lórí ní Èko àti ní ibòmíràn; ó sì yẹ ká mọ̀ ọ́ kà, ká sì mọ̀ ọ́ kọ. Òwe tí ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi kọ́ wà láti tọ́jú ti ara ẹni, nítorí náà kò yẹ, kò sì tọ́ kí fífọ èdè gẹ̀ẹ́sì kó gba gbogbo ipá wa, tàbí kí ìfẹ́ tí a ní sí i kó tì wá láti kọ èdè wa sílẹ̀, nítorí pé èdè ìyá ẹni dára ju ti ẹlòmíràn lọ. Àti gidi pàá, a kò lè di ẹni ńlá tàbí ẹni alágbára nípa fífọ èdè ẹlòmíràn, bí ẹrú ni a máa rí títí.
A ó sọ èyí pẹ̀lú pé, ní gbígbé ìwé yìí kalẹ̀ fún àwọn ọmọ ìlú wa, a kò fi ọwọ́ sọ̀yà pé ohun titun kan wà nínú rẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbọ́ rí, ṣùgbọ́n a gbìyànjù láti kó pàtàkì òwe jọ síbì kan, èyí tí a ńlò lójojumọ́ ní ilẹ̀ wà.
Gẹ́gẹ́ bí àlọ́ ti ní ìtàn, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òwe ní; kò sí ìtàn nínú ìwé yìí; a kò tíì múra rẹ̀, bóyá ó lè yọ ní ọjọ́ míìràn. Ṣáájú èyí, a lè sọ gbangba pé a kò mọ̀ ẹnìkan tí ó ṣe irú ìwé yìí rí; alàgbà Samuel Crowther, ọmọ-ìbílẹ̀ wa, ẹni tí í ṣe ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ẹni Olóyè gíga nínú ẹgbẹ́ tí a ńpè ní Church Missionary Society, òun ni ẹni tí ó ní òwe díẹ̀ nínú ìwé gbédègbeyọ̀ rẹ̀, ìwé tí àwọn òyìnbó ńpè ní Vocabulary; ṣùgbọ́n níhìn-ín ni a kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe jọ nínú àwọn òwe ilẹ̀ wa, tí a sì rán wọn sí àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ wa láti máa lò. Ara òwe Bishop Crowther náà wà níhìn-ín pẹ̀lú.
Ìṣẹ̀dálẹ̀ Yorùbá ni pé, ọmọdé kìí pa òwe; bí ọmọdé yóò bá pa òwe, yóò júbà àgbà kó tó pa á. Àṣà yìí kó tíì parẹ́ títí di òní. Òwe wúlò ní ọ̀rọ̀ sísọ àti ní píparí ìjà; àgbà mìíràn wà tí kò lè sọ̀rọ̀ pẹ́ títí lí àìpa òwe méjì tàbí mẹ́ta sí i; bí a bá sì lo òwe lọ́nà búburú, a má díjà sílẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ òwe dára púpọ̀, a kò sì lè sọ òkòròkoro rẹ̀ tó bí a ti pa á sí ẹ̀yìn ìwé yìí pé,
“Òwe ni ẹṣin ọ̀rọ̀,
bí ọ̀rọ̀ bá sọnù,
òwe ni a fi í wá a”
Mo ní ìrètí pé ní ọjọ́ àìpẹ́ sí i, àwọn ẹlòmíràn yóò gbìyànjú, a ó sì ní onírúurú ìwé mìíran ní èdè wa; ìwé iṣẹ́ ṣíṣe, ìwé ọjà títà, ìwé ọgbọ́n orí, ìwé ìgbàgbọ́ ọkàn, àti ohun mìíràn.
Mo sì rò pé ó yẹ kí a jẹ́ kó yé àwọn tí yóò ka ìwé yìí pé, nínú ìwé yìí, gbogbo ìlú Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Àwórì, ìlú àwọn Ọ̀yọ́, àti ìlú àwọn Èkìtì, ni à ńpè ní ilẹ̀ Yorùbá.
Àdúrà àti ìfẹ́ mi ni kí ìwé yìí lè túbọ̀ fi ìfẹ́ àti máa ka ìwé Yorùbá lélẹ̀ láarin wa. Ó di sáà kan, “aládùúgbò kìí dá ọ̀la”
S.A. ALLEN
Jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ ní èdè Ẹgbá tí a bí mi sí. Lóòtọ́ lí ó jẹ́ pé ìyà ìwé kíkọ jẹ àwọn aṣíwájú lógún jọjọ tóbẹ́ẹ̀ tí kálukú àwọn yí límọ̀ nígbà yẹ̀n fí ṣiṣẹ́ agbógoyọ Yorùbá lípa kíkọ ìwé lí èdè Yorùbá. Bí ìyà àìsí ìwé tí jẹ àwọn èrò íṣáájú, kó ta wọ́n lípàá, bẹ́ẹ̀ nẹ re ọ ṣe rí láyé tiwa yìí. ihun burú jù líbẹ̀ re pée lẹ́sẹ̀nyìí, ìwé ti pọ jaburata, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀dọ̀ àti àgbà pàápàá kò likàn orí rẹ̀ ṣe: éèsí ẹni fẹ́ kàwé mọ́ dépo pé wọn a lá ràwé òwé kàn. Ìyẹ̀n re burú jù.
ReplyDeleteẸ ṣeun, Ọ̀mọ̀wé Ṣóẹ̀tán. Ní tòótọ́, ìwé pọ̀ lọ́jà lónìí ju ti 1885. Ṣùgbọ́n tí a bá fí ọjà ìwé ní èdè Yorùbá wé tí èdè òyìnbó ní Nàìjíríà nìkan, ká fi í sẹ́nu ká dákẹ́ ni o. Ní báyìí, ó jọ bí ẹni pé iná sinimá, fídíò, àti orin ìgbàlódé gan-an, lédè Yorùbá kò yaki tó ti tẹ́lẹ̀. Lérò tèmi, àìgbédè, èyí tó fà àìmọ̀ọ́kà, àìmọ̀ọ́wò, àti àìmọ̀ọ́gbọ́, ló ń ńbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jà. Ire o.
Delete