Aṣọ Tàbí Ènìyàn? Lẹ́dà kan, mo gbọ́ pé, aṣọ ńlá kọ́ lènìyàn ńlá. Lẹ́dà kejì wọ́n tún fi yé mi pé aṣọ là ńkí, a à kí ‘nìyàn. (Ẹnu kòfẹ́sọ̀ àgbà kan ni mo tí kọ́kọ́ gbọ́ eléyìí ní nńkan bí ogún ọdún sẹ́hìn.) Èwo ni ká wá ṣe o? Èwo ni ká tẹ̀lé? Èwo ni ká gbàgbọ́. Gbólóhùn méjèèjì ha le jẹ́ òótọ́ bí? Àtakò kọ́ rèé! Ó dá mi lójú pé àfiwé ni gbólóhùn méjèèjì. A tilẹ̀ lè pé wọ́n lówe. Gbogbo wa la sì mọ̀ pé àfiwé kìí ṣe òfin. Àfiwé yàtọ̀ sí ìṣẹ̀dálẹ̀. Òwe kìí ṣe orò. Àfiwé le jẹ́ àbàláyé. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tàbí ìmọ̀ tí àfiwé bá gbéró máa ńyí padà lóòrè kóòrè. Òjó yàtọ̀ sí òjò. Mẹ́táfọ̀ yàtọ̀ sí òtítọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ lè farasin sínú mẹ́táfọ̀. Ẹ̀ràn yàtọ̀ sí irọ́. Kò sí ẹ̀dá alààyè àti olóye kankan tí kò mọ̀ pé aṣọ kìí ṣe ènìyàn, tàbí wí pé ènìyàn yàtọ̀ sí aṣọ. Dídá lènìyàn ńdá aṣọ tàbí ẹ̀wù. A kìi dá ènìyàn bí ẹni ńdáṣọ. Ènìyàn lè wọ aṣọ tàbí ẹ̀wù. Èmi kò rò pé aṣọ lè wọ ènìyàn bí è...
Comments
Post a Comment