Photo: Ògbógi. by Adélékè Adéẹ̀kọ́
|
Lọ́sẹ̀ bíi mélòó kan sẹ́hìn, "Èrò Ni Gbẹ̀gìrì" ṣe ìlérí àgbéyẹ̀wò orísun ẹ̀tọ́. Bí iṣẹ́ kò bá pẹ́ ni, a kìí pẹ́ iṣẹ́.
1: Òfin jẹ́ orísun pàtàkì fún ẹ̀tọ́. Àwùjọ ẹ̀dá ni ó máa ńfòfin lélẹ̀ lórí ohun tí a lè ṣe, àti bí a ti lè ṣe wọ́n. Ohun tó bófin mu máa ńsábà jẹ́ ohun tó lẹ́tọ̀ọ́. Ohun tí ó lòdì sófin le má lẹ́tọ̀ọ́. Ènìyàn ni òfin máa ńdè. Òfin kìí mú igi, kìí mú ọ̀pẹ, kìi ́mú ẹranko. Òfin le mú olúwa àwọn nǹkan wọ̀nyí. (Bí ajá bá tilẹ̀ rò pé òun là ńbẹ̀rù, gbogbo wa la mọ̀ pé alájá là ńbọ̀wọ̀ fún.) Ẹ̀dá kankan kò lè ṣòfin fúnra rẹ̀ tàbí fún àwùjọ láì jẹ́ wípé ìlú fún un láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí já sí pé òfin gbọdọ̀ ní àtìlẹ́hìn àṣẹ gbogboògbò. Ìlú, tàbí aláṣẹ, gbọdọ̀ lágbára láti lè mú òfin ṣẹ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀tọ́ kò ní lójútùú. A lè pe òfin ní ìmúṣẹ ìfẹ́ ìlú tàbí àwùjọ.
2. Àṣà, tàbí gbogbo ìlànà ìbáṣepọ̀ tó bójúmu láwùjọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kìí ṣe òfin, le jẹ́ orísun ẹ̀tọ́. Fún àpẹrẹ, nígbà wo ló bójú mu láti dáná alẹ́? Nígbà wo làá pàlọ́? Irú oúnjẹ wo ni Mùsùlùmí lè fi túnu ààwẹ̀? Irú ẹ̀wù wo làá wọ̀ lọ síbi iṣẹ́? Ìbójú mu ní òṣùnwọ̀n àṣà. Ohun tó bá bójú mu, a máa bá ẹ̀tọ́ mu. Ènìyàn tí kò mọjú ti kò mọra le má rú òfin rárá; ṣùgbọ́n aláìmẹ̀tọ́ ní onítọ̀hún. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé òbí tí kò bá tọ́mọ sọ́nà ńṣàìtọ́, ó ṣeéṣe kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ má rú òfin kankan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèwọ̀ jẹ mọ́ àṣà. A lè fi ìlànà ẹ̀sìn, ojúṣe, orò, ìṣẹ̀dálẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, sábẹ́ ìsọ̀rì àṣà.
3. Ẹ̀rí ọkàn ni aláyélùwà ẹ̀tọ́. Èyí ṣe jẹ́? Ẹ̀rí ọkàn ni alákòóso agbára, ìfẹ́, àti ìṣe. A máa ńrú òfin tí ẹ̀rí ọkàn bá sọ fún ni pé òfin ọ̀hún kò bá ẹ̀tọ́ mu. Fún àpẹrẹ, gbogbo òfin amúnisìn lòdí sí ẹ̀tọ́ torí ìpalára tí wọ́n máa ńṣe fún ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn. Àìlẹ́tọ̀ọ́ rọ̀ mọ́ gbogbo àṣà tí kò bá bọ̀wọ̀ fún ọmọnìyàn, tí ẹ̀rí ọkàn fi yé ni pé ó ńfa ìnira àìmọwọ́-àìmẹsẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì, ìrẹ́nijẹ, tàbí ìbànújẹ́. Ẹ̀rí ọkàn a máa darí wa láti kọ ẹ̀yìn sí òfin tàbí àṣà tó gba irúfẹ́ ìwà àti ìṣe bẹ́ẹ̀ láyè.
Lọ́sẹ̀ tó ńbọ̀, ìjíròrò wa yóò dá lérí ikú. Ó dìgbà kan ná. Láyọ̀ o.
Comments
Post a Comment