Òwe ni àkọ̀lé yìí. Kódà, ìfohùndárà sọjọ̀ síbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká jọ ṣe àyẹ̀wò àwọn kókó inú rẹ̀, pàápàá jùlọ fún ọ̀ràn tí gbólóhùn yìí lè dá sílẹ̀ lórí ìṣebaba. Òwe yìí da lúúrú ètò ìgbà tàbí àsìkò mọ́ ti ètò ibùgbé, ó sọ màrìwò dorò mọ́ gbogbo wa lọ́wọ́. Orò sì rèé, ó yàtọ̀ sí màrìwò.
Òótọ́ ni wípé ẹni tí a bá níbùgbé kan ṣáájú àwọn tó dé lẹ́hìn rẹ̀. Nípa èyí, a kò le ya àsìkò kúrò lára ìgbàyè. Gbólóhùn tó sọ pé ẹnì kan bá ẹlòmíràn lábà ńjẹ́rìí àdámọ́ ìgbà àti ibùgbé ni. Kò sí àríyànjiyàn lórí eléyìí. Ṣùgbọ́n bí a bá wá ṣe àfikún, tí a so irun iwájú ṣísẹ̀ntẹ̀lé mọ́ ti ìpàkọ́ ètò ìbí, tí a kéde pé ẹni a bá lábà ni baba, nǹkan mìn ín ìn ti wọ̀ ọ́. A sì gbọdọ̀ gbé e yẹ̀wò.
Àlùwàlá ológbò àwọn àgbà tí ó pe ‘ra wọ́n ni baba ni òwe yìí tó sọ àkíyèsí ìṣesí àti àṣà dòfin; ọgbọ́n ni láti fi ṣe ìrẹ́jẹ fún àwon tí kìí ṣe baba. Kedere ló hàn, títí tó fi délẹ̀ kòwárí, pé àgbà, yálà bàbá tàbí ìyá, ọkùnrin tàbí obìnrin, ṣáájú èwe. Ṣùgbọ́n gbólóhùn àgbéyẹ̀wò wa ti so okó mọ́ ìdí ìṣáájú. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tó yẹ kó wí ni pé ẹni a bá lábà làgbà, tàbí ẹni a bá lábà ni aṣáájú, tàbí ẹni a bá lábà lẹ̀gbọ́n.
Ẹni a bá lábà ṣe jẹ́ baba? Ètò ìgbóbìnrin níyàwò wá sílé ọkùnrin ló ṣe okùnfà gbólóhùn yìí. Báwo lèyí ṣe jẹ́? Káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, ìlànà ìgbéyàwó ni pé kí obìnrin lọ sílé (tàbí abà) ọkọ tí a fẹ́ ẹ sí. Kò wọ́pọ̀ kí a fẹ́ ọkùnrin lọ sílé (tàbí abà) obìnrin. Ẹ má ṣi mí gbọ́ o; mi ò sọ pé òfin ìsẹ̀ńbáyé kan wà tí mo mọ̀ tó dènà ìrú ìṣe bẹ́ẹ̀ o.
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ wípé iwájú ni ọ̀pá àkokò má a ńré sí, tí ó sì jẹ́ pé ẹni tó bá kọ́kọ́ dé ibùdó kan kò lè ṣàì ṣáájú àwọn tó dé lẹ́hìn rẹ̀, tí ó sì tún jẹ́ pé ẹsẹ̀ ìran akọ ni ìran abo ńtọ̀ láti di aya nínú ilé (abà) míràn, kò sí ni kí akọ má ṣíwájú ní ìlànà ìgbà àti àsìkò. Ètò yìí sì sọ abà akọ di ibùgbé fún tọkọtaya. “Patrilocality” ni mo gbọ́ pé àwọn ọ̀mọ̀wé onígẹ̀ẹ́sì ńpè é.
Ètò yìí so ibùgbé pọ̀ mọ́ àsìkò, ìṣobìnrin, ìṣọkùnrin, ìṣọkọ, ìṣaya, àti ìṣọmọ bákan náà. Ṣé ìsopọ̀ kò dáa ni? Kódà, Dàda kò dáa tó o! Ìdààmú tó wà níbẹ̀ ní wípé, àsopọ̀ yìí kò dọ́gba. O sọ akọ di aṣáájú láì nidìí. Abo di àtẹ̀lé àpàpàǹdodo. Ó sì tún fi òté lé e pé bẹ́ẹ̀ ni yóò máa rí títí láéláé.
Àkọ́dé ṣe wá di akọ, nígbà tí ó jẹ́ pé okó kọ́ la fi ńdi aṣájú? Ẹ jẹ́ kí ńṣe àlàyé díẹ̀ sí i. Mo mọ̀ pé ẹni tí a bá gbé níyàwó lọ sílé ọkọ kò fi ipò aṣájú sílẹ̀ nílé tí a ti bí i. Òótọ́ lèyí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Òyéwùmí ti ńlu agogo èyi láti ọjọ́ gbọ́n-un. Nílé e bàbá tàbí ìyá tó bí i, àgbà labo jẹ́ fún àwon àbúrò rẹ̀ àti fún àwọn ìyàwó ilé àti fún àwọn tí wọ́n wá láti abà míràn. Baba ni wọ́n jẹ́ níbẹ̀. Kí wá ni ìdí tí wọn kò fi lè jẹ́ baba nílé ọkọ wọn? Abo kò lè jẹ́ baba fún ẹnikẹ́ni nílé oko rẹ̀. Kódà, abo kò lè jẹ́ baba fún ọmọ bíbí rẹ̀ níbẹ̀. Nílé àwọn òbí rẹ̀, ó le jẹ́ baba fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, wọn ìbá à jẹ akọ, wọn ìbá á jẹ abo. Èyi já sí pe okó kọ́ ní ńsọ ni di baba.
Ọkùnrin lè di baba fún àwọn ọmọ bibi rẹ̀, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, nínú ilé tàbí abà tí a bí i sí, tàbí tí wọ́n ti sọ ọ́ di ọmọ. Wọn kò lè ṣe, tàbí jẹ́, ìyá fún ẹnikẹni níbẹ̀. Ìdílé ìyá wọn nìkan ni wọ́n ti lè jẹ́ ìyá láàrin àwọn ọmọ mòlẹ̀bí. Níbẹ̀, wọn kò lè jẹ́ ìyà fún ọmọ bíbí tara wọn.
Níparí, abẹ́ ètò ìṣèlú baba-ló-làṣẹ nìkàn lati lè sọ pé ẹni a bá lábà ni baba. Lábẹ́ ìṣèlú olómìnira, kóńkó-jabele, kólórí-dorí-ẹ̀-mú, ọ̀tọ̀ lokó, ọ̀tọ̀ loko, ọ̀tọ̀ laṣáájú. Okó kọ́ la fií ṣe baba, ọmú kọ́ la fi í ṣe ìyá.
Àkọ́dé àti aṣáájù, yálà akọ tàbi abo, ẹgbẹ́’ra ni wọ́n.
Bi a ba gba itumo tee lo ninu apileko yii, pe itumo baba ni okunrin to fi okoo re bimo, ko si ariyanjiyan ninu ede tee pe. Amo niwon igba ti ede Yoruba ko yato si awon ede miiran ti awo eya eda mii n so, ti a si mo wi pe, ko wopo ninu edekede pe itumo kan ni awon oro inu ede n ni, a gbodo kiyesi pe ninu ede Yoruba naa, ko seese pe ki a ri awon oro pupo ninu ede naa ti won ko ni ju itumo kan lo.
ReplyDeleteBee gege lo ri ninu ede Yoruba. "Baba" ni ju itumo kan lo. Yato si "okunrin ti o bi omo" awon itumo miiran niyi: "agba"; "onimo ninu ise tabi owo tabi ise sise pato, fun apere, onilu, onisona, abbl. Baba ogun ni Balogun sugbon kii se nipase omo bibi logun lo fi je baba ogun; bee naa ni babalawo.
"Baba" ninu asayan oro te n se iwadii re, ko je mo "baba omo" rara. Eni taa ba laba ti ko mona, ti ko mo bi a se n se laba, ti oye re lori ohun ti n sele laba ku die kaato, kii se iru eni ti a maa n so pe "Baba ni laba". Kii se atetede nikan la fi n di baba laba. Ogbon iselu, imo nipa ohun ti n lo laba, wiwa nipo eni ti a le lo ba fun imoran ati ilana bi eniyan ti n se laba lai sise, to le to ni sona nipa ilo ati ise, ni kukuru, asa aba naa, ni baba.
E gba kan si i; asayan oro yii ko so baba laba je tabi pe o ni lati je okunrin. Niwon igba ti a ba ti gba, e si toka si i ninu apileko yin, pe kii se gbogbo eni ti a ba pe ni baba ni okunrin, o ye ka ni idaju pe asayan oro yii ko fi okunrin gaba lori obinrin.
Se mo wiire? Ire o.
Ẹ ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n Ìmọ́dòye. Àìwíire ti jẹ́! Abọrẹ̀ lẹ̀yin, àyàfirere nìkàn. Èdè kan náà la sì jọ ńfọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà. Níparí búlọ́ọ̀gì yìí, mo kọ ọ́ pé, "Okó kọ́ la fií ṣe baba, ọmú kọ́ la fi í ṣe ìyá." Aáyan mi dá sórí ìtúpalẹ̀ ìjọba baba-ló-làṣẹ tí àwọn kan sọ pé ó jẹ́ àdámọ́ láti ìgbà ìwáṣẹ̀ nílẹ̀ẹ Yorùbá, àwọn tí wọ́n sọ òwe àti àfiwé di òfin ìṣẹ̀ṣe.
Delete