Léròo tèmi, ìṣe nìkàn fúnra rẹ̀ kò tó gẹ́gẹ́ bí òṣùnwọ̀n ẹ̀tọ́ nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣe ni kò tọ̀nà, àìmọye ìṣe ni wọ́n ṣàìtó. Níwọ̀n ìgbà tó ṣeéṣe kí a rí ìṣe tí kó bá ẹ̀tọ́ mu, a jẹ́ wípé ohun tí ńdarí ẹ̀tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí ńdarí ìṣe. A kò lè rí ẹ̀tọ́ gbámú ní pọ́nbélé láì jẹ́ pé ó jẹyọ lára ìṣe. Ìṣe rèé, ọmọlangidi ni; ó tọ́ o, kó tọ́ o, oníṣe kò ní ṣàì ṣe. Ìṣe yóò ṣe bí ó bá ti wu oníṣe. Bí oníṣe bá ti pé “ó yá,”, ẹ̀tọ́ ṣetán o, ẹ̀tọ́ kò ṣetán o, ìṣe yóò jẹ́ ìfẹ́ oníṣe nípè. Agbára ìṣe àti ìfẹ́ nìkàn ti tó fún ìṣe láti ṣe. Ẹ̀tọ́ nílò ẹ̀rí ọkàn àti, tàbí, òfin tí ó rọ̀ mọ́ èròǹgbà àtí ìfẹ́ ẹ̀dá oníṣe. Èyí túmọ̀ sí wí pé ìṣe ẹlẹ́tọ̀ọ́ so mọ́ nńkan méjì: (i) oníṣe gbọdọ̀ mọ̀ọ́ mọ̀; (ii) àmúṣe tí kò lẹ́tọ̀ọ́—èyí tí àbáyọrí rẹ̀ lè kú sí èṣe, ẹ̀ṣẹ̀, ọ̀ràn—máa ńlẹ́hìn, yálà oníṣe mẹ̀tọ́ọ̀ tàbí kò mẹ̀tọ́, bóyá onítọ̀hún fetí sí ẹ̀rí ọkàn tàbí ó kọtí ọ̀gbọnin s...