Skip to main content

Ẹ̀tọ́ àti Ìṣe (1)






Léròo tèmi, ìṣe nìkàn fúnra rẹ̀ kò tó gẹ́gẹ́ bí òṣùnwọ̀n ẹ̀tọ́ nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣe ni kò tọ̀nà, àìmọye ìṣe ni wọ́n ṣàìtó. Níwọ̀n ìgbà tó ṣeéṣe kí a rí ìṣe tí kó bá ẹ̀tọ́ mu, a jẹ́ wípé ohun tí ńdarí ẹ̀tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí ńdarí ìṣe.

A kò lè rí ẹ̀tọ́ gbámú ní pọ́nbélé láì jẹ́ pé ó jẹyọ lára ìṣe. Ìṣe rèé, ọmọlangidi ni; ó tọ́ o, kó tọ́ o, oníṣe kò ní ṣàì ṣe. Ìṣe yóò ṣe bí ó bá ti wu oníṣe. Bí oníṣe bá ti pé “ó yá,”, ẹ̀tọ́ ṣetán o, ẹ̀tọ́ kò ṣetán o, ìṣe yóò jẹ́ ìfẹ́ oníṣe nípè. Agbára ìṣe àti ìfẹ́ nìkàn ti tó fún ìṣe láti ṣe. 

Ẹ̀tọ́ nílò ẹ̀rí ọkàn àti, tàbí, òfin tí ó rọ̀ mọ́ èròǹgbà àtí ìfẹ́ ẹ̀dá oníṣe. Èyí túmọ̀ sí wí pé ìṣe ẹlẹ́tọ̀ọ́ so mọ́ nńkan méjì: (i) oníṣe gbọdọ̀ mọ̀ọ́ mọ̀; (ii) àmúṣe tí kò lẹ́tọ̀ọ́—èyí tí àbáyọrí rẹ̀ lè kú sí èṣe, ẹ̀ṣẹ̀, ọ̀ràn—máa ńlẹ́hìn, yálà oníṣe mẹ̀tọ́ọ̀ tàbí kò mẹ̀tọ́, bóyá onítọ̀hún fetí sí ẹ̀rí ọkàn tàbí ó kọtí ọ̀gbọnin sí i, bóyà ó mòfin, tábí kò mòfin.

Ìbéèrè: (1) Ǹjẹ́ ẹ̀tọ́ lè dínà tàbí dènà ìṣe? (2) Ǹjẹ́ ìṣe le dínà tàbí dènà ẹ̀tọ́? (3) Kínni ìbáṣepọ̀ ẹ̀tọ́ àti ìṣe? Aáyan ìdáhùn dijọ́ miǹínìn, ọjọ́ọ’re. 

Èrò ni gbẹ̀gìrì, bá à bá rò ó, kò níí ki. Ire o. 

Comments

Popular posts from this blog

One Thought About Textual Beginnings: Ìbà

ÌJÚBÀ or ÌBÀ (noun); JÚBÀ (verb)   The initial gestures rendered to acknowledge authority figures, sacral or secular, to which a performance production owes its textual and institutional provenance constitute the ìjúbà (ìbà). The conventional words and motions thus presented demarcate the commencement of an iteration, pay homage to sources of influence and inspiration, praise past patronages, solicit audience support and understanding, wish failure for opposing will and interests, and outline the production’s goals. HISTORY Two paths stand out in the historical understanding of ìjúbà: one follows the older, text based line in translation manuals and dictionaries, and the other issues from scholarly studies of performance traditions. Although they are more recent and offer longer overviews that extend far back into mythical times, scholarly studies of ìjúbà lean heavily on old traditions recounted in explanations of contemporary enactments, mainly of egúngún and gẹ̀lẹ̀de...

Aṣọ Tòun Tènìyàn

Aṣọ Tàbí Ènìyàn? Lẹ́dà kan, mo gbọ́ pé, aṣọ ńlá kọ́ lènìyàn ńlá. Lẹ́dà kejì wọ́n tún fi yé mi pé aṣọ là ńkí, a à kí ‘nìyàn. (Ẹnu kòfẹ́sọ̀ àgbà kan ni mo tí kọ́kọ́ gbọ́ eléyìí ní nńkan bí ogún ọdún sẹ́hìn.) Èwo ni ká wá ṣe o? Èwo ni ká tẹ̀lé? Èwo ni ká gbàgbọ́. Gbólóhùn méjèèjì ha le jẹ́ òótọ́ bí? Àtakò kọ́ rèé! Ó dá mi lójú pé àfiwé ni gbólóhùn méjèèjì. A tilẹ̀ lè pé wọ́n lówe. Gbogbo wa la sì mọ̀ pé àfiwé kìí ṣe òfin. Àfiwé yàtọ̀ sí ìṣẹ̀dálẹ̀. Òwe kìí ṣe orò. Àfiwé le jẹ́ àbàláyé. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tàbí ìmọ̀ tí àfiwé bá gbéró máa ńyí padà lóòrè kóòrè. Òjó yàtọ̀ sí òjò. Mẹ́táfọ̀ yàtọ̀ sí òtítọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ lè farasin sínú mẹ́táfọ̀. Ẹ̀ràn yàtọ̀ sí irọ́.   Kò sí ẹ̀dá alààyè àti olóye kankan tí kò mọ̀ pé aṣọ kìí ṣe ènìyàn, tàbí wí pé ènìyàn yàtọ̀ sí aṣọ. Dídá lènìyàn ńdá aṣọ tàbí ẹ̀wù. A kìi dá ènìyàn bí ẹni ńdáṣọ. Ènìyàn lè wọ aṣọ tàbí ẹ̀wù. Èmi kò rò pé aṣọ lè wọ ènìyàn bí è...

Ọlábíyìí Babalọlá Joseph Yáì (1939-2020)

Decolonization Without a Linguistic Turn  is Like  Drinking Sugar Without Tea:  Ọlábíyìí Babalọlá Joseph Yáì (1939-2020) Read article Here