| A Gathering of Feet | Photo by Tòkunbọ̀ Ọlálẹ́yẹ́ 1: Èrò kan ti ńjẹ mí lọ́kàn fún bí sáà mélòó. Ọ̀rọ̀ náà dá lórí ìfunpè àkíyèsí, àti ìfura, nípa ìlànà ìgbáyé ati ìgbàyè tí à ńpè ní Yorùbá lónìí, pàápàá ti àwọn aṣáájú ẹlẹ́sìn àti aláṣà nínú ìrísí yìí. Ẹṣin akitiyan tí mò ń wí jẹ mọ́ ìṣẹ̀ṣe. Bó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ìṣẹ̀ṣe ni. Èdè sísọ, ìṣẹ̀ṣe Yorùbá ni. Bó bá di ẹ̀ṣọ́, ìbáà jẹ́ ti ara, ìbáà jẹ́ ti oun mìíràn, ìṣẹ̀ṣe ni. Bó jẹ́ ìṣèlú, ìṣẹ̀ṣe yìí kan náà ni a máa ńké pè. Díẹ̀ lásán ni mo kà sílẹ̀ yìí. Ìṣèṣe sì kọ́ ló ńdà mí lọ́kàn rú. Ìhà tí àwọn oníṣẹ̀ṣe kọ sí ìṣẹ̀ṣe ló ńkọ mi lóminú nítorí pé, wọ́n ti sọ ìṣẹ̀ṣe fún’ra rẹ̀ di ká-bi-yín-ò-sí, wọ́n si fi òté bó-ṣe-wà-látètèkọ́ṣe dí i lẹ́nu. 2: Èmi a máa bá àwọn oníṣẹ̀ṣe jiyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ látàrí wípé wọ́n mọ odi àsàmọ̀sì yí abala oríṣi ìṣe kan ká, wọ́n sì pè é ní ìṣẹ̀ṣe. Abala tí wọ́n mọ odi ká náà kìí fọhùn, kìí fèsì ìbèrè láì fara ya, kì...