Photo: Ògbógi. by Adélékè Adéẹ̀kọ́ Lọ́sẹ̀ bíi mélòó kan sẹ́hìn, "Èrò Ni Gbẹ̀gìrì" ṣe ìlérí àgbéyẹ̀wò orísun ẹ̀tọ́. Bí iṣẹ́ kò bá pẹ́ ni, a kìí pẹ́ iṣẹ́. 1: Òfin jẹ́ orísun pàtàkì fún ẹ̀tọ́. Àwùjọ ẹ̀dá ni ó máa ńfòfin lélẹ̀ lórí ohun tí a lè ṣe, àti bí a ti lè ṣe wọ́n. Ohun tó bófin mu máa ńsábà jẹ́ ohun tó lẹ́tọ̀ọ́. Ohun tí ó lòdì sófin le má lẹ́tọ̀ọ́. Ènìyàn ni òfin máa ńdè. Òfin kìí mú igi, kìí mú ọ̀pẹ, kìi ́mú ẹranko. Òfin le mú olúwa àwọn nǹkan wọ̀nyí. (Bí ajá bá tilẹ̀ rò pé òun là ńbẹ̀rù, gbogbo wa la mọ̀ pé alájá là ńbọ̀wọ̀ fún.) Ẹ̀dá kankan kò lè ṣòfin fúnra rẹ̀ tàbí fún àwùjọ láì jẹ́ wípé ìlú fún un láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí já sí pé òfin gbọdọ̀ ní àtìlẹ́hìn àṣẹ gbogboògbò. Ìlú, tàbí aláṣẹ, gbọdọ̀ lágbára láti lè mú òfin ṣẹ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀tọ́ kò ní lójútùú. A lè pe òfin ní ìmúṣẹ ìfẹ́ ìlú tàbí àwùjọ. 2. Àṣà, tàbí gbogbo ìlànà ìbáṣepọ̀ tó bójú...