Skip to main content

Posts

Showing posts from October, 2020

Kọ́lẹ́ẹ́jì Onígbá Méjì Láti Ọwọ́ Fẹ́mi Ọ̀ṣọ́fisan: Ìfáárà

Bí a Tilẹ̀ Ń Sunkún, A Kìí Ṣài Ríran!   Lọ́dun 1975 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ Kolera Kolej , àkọlé tí a túmọ̀ sí Kọ́lẹ́ẹ̀jì Onígbá Méjì nínú ìwé yìí. Ilé iṣẹ́ aṣèwé New Horn Press ní ìlú Ìbàdàn ló gbé e jádé . Òun sì ni ìwé ìtàn aláròsọ àkọ́kọ́ láti ọwọ́ Fẹ́mi Ọ̀ṣọ́fisan, ẹni tí gbogbo olóye ènìyàn mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀jọ̀gbọ́n àti òǹkọ̀wé jàǹkàn. Eré aláṣehàn lórí ìtàgé ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣọ́fisan gbajúmọ̀ fún. Ṣàṣà ènìyàn ló mọ Ọ̀ṣọ́fisan ní olùkọ̀tàn. Kòtóǹkan ni iye ẹni tó mọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀ṣọ́fisan gẹ́gẹ́ bí eléwì. Ṣùgbọ́n òǹkàwé tó bá fojú inú wo Kólẹ́ẹ̀jì Onígbá Méjì yóò rí i pé àṣehàn pọ̀ fún àwọn ẹ̀dá inú ìtàn náà; kódà bárakú ni ìṣe onídan jẹ́ fún èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èrò Onígbáméjì àti Oríle Iyá. Síwájú sí i, kò sí bí òǹkàwé kò ṣe ní kíyèsí ipa pàtaki ti ọ̀jọ̀gbọ́n akéwì, ẹ̀dá tó fẹ́ràn ajá rẹ̀ ju ènìyàn lọ, kó nínú ìtàn yìí. Ní tòótọ̀, ẹni wa fẹ́ràn obínrin dé góńgó; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó ní sí ajá rẹ